Oriki Orile

HomeOriki Orile

The Oríkì Orilè is the ancestral praise poetry of the Onigbanjo lineage, tracing descent from the Ìresà people. Recited at naming ceremonies and family gatherings, it identifies the family's spiritual and historical roots

Oriki Orile Ijaiye

The ancestral praise poetry of the Onigbanjo lineage

The Iresa Lineage

Emi ni ara Iresa
Ara Iresa omo oba dun
Omobadun Oroshoki
Omobadun Ekoro
Omo mi o seni, mi o seni ni o bi ara Iresa nu,
Wole kogbe koto loya omode lara.
Inabo laida gun, baba mi romini joye Aresa
Omo kutukutu ni, mi bati ba eru budo dele.
Wole ogbe koto niya omode lara.

The Valor and Heritage

Bi o sin ye pa, bi o sin segi pelu ata were ni jo loju abuni.
Ero mi koye elegan rara.
Omo dudu legbon, pupa laburo,
Omo o sun lataro pe lori eni.
Omo a jima sin enikan, fantifanti nisanra e.
Emi ni omo Ikoyi Akoko.
Emi ni omo Arogun Mamasa.
Omo tatabulu, omo olowo ilanla to silekun fun ole.

Discover your heritage. Preserve your traditions.
Represent all that makes you.